Onibeere: Ahmad
Eyin onimimo, Asalamu alaykum. Ejowo e se alaye nipa osu Rajab, ati wipe kini itumo gbolohun “Rajab”? Nje awon ijosin kan wa ti o ye ki a maa se ninu osu yii? Olohun a san ni esan oloore.
Idahun:
Sheikh Ahmad Ash-Sharabasi
Wa `alaykum as-salamu wa rahmatullahi wa barakatuh.
Ni Oruko Olohun Oba Ajoke Aye , Oba Asake Orun. Ope ni fun Olohun , Ike ati ige ki o maa ba Asiwaju eda Muhammad.
Omo iya wa ninu Islamu, adupe pupo lowo yin fun ibeere yii, eleyi ti o nfi daniloju wipe eko islamu se pataki ni okan yin. Bakanna ni e si nfe lekun ninu eko Islamu.
Read Also:
|
Owo ati iyi ti o wa fun awon Masalasi meteta paapajulo Masalasi Qudusu ti ilu Palastine ti awon Israel elesin Yahuudi je gaba le lori.
Lekun rere si oro yii, agba alufa Sheikh Ahmad Ash-Sharabasi, oluko imo oye ati adisokan, ile-iwe giga Al-Azhar, so wipe:
Ninu awon osu Larubawa ati Islamu ni Rajab wa. Gbolohun rajab wa lati ibi tajrib, eleyii ti o n tumo si yiyin ati fifi ogo fun, awon Larubawa a maa fun osu yii ni owo ati aponle pupo, idi niyii ti won fi npe ni orukorajab.
Raja Osu Owo
Awon Larubawa a ma pe osu yii ni osu owo, tori wipe ninu awon osun owo merin ni o wa, eewo sini fun fun enikeni lati ba ara won ja tabi tae je sile ninu awon osu yii.
Olohun so nipa awon osu owo ninu Al-kurani Alaponle wipe:
{ Dajudaju onka awon osu ni odo Olohun je osu mejila ninu Tira Olohun lati ojo ti O ti da sanma ati ile na, osu merin ti o je abowo nbe ninu re. Eyini ni esin ti o duro deede nitorina e mase abosi funra nyin ninu won. Ati ki e si maa ba awon osebo ja patapata gegebi nwon ti se ba nyin ja patapata ki e si mo amodaju pe Olohun nbe pelu awon olupaiya (Re).} (Suratu Taobah 9: 36).
Awon osu owo yii Dhul-Qi`dah, Dhul-Hijjah, Muharram ati Rajab
Rajab Alaso
Bakana won tun ma pe osu yii ni osun aso (Rajab Al-Fard). Idi ni wipe osu yii da yato ninu awon osu owo meta toku, leyin osu marun ti awon osu owo meteta akoko ba lo tan- Dhul-Qi`dah, Dhul-Hijjah ati Muharram ni osu Rajab ma nde.
Ninu osu alaponle yii ni irin-ajo nla Al-Israa' and Al-Mi`raj wa ye, irin-ajo ti Olohun fi se alekun aponle ati iyi fun Anabi Re |
Beeni, won tun ma pe osu yii ni Rajab Mudar, oruko yii waye ninu Adisi Anabi Muhammad (Ike Olohun ki o ma baa) ti o so wipe: “..Ati (osu elekerin) Rajab (ti idile Mudar) osu eleyii ti o wa laarin osu Jumada (Thani) ati osu Sha`ban”.
Idile kan ni Mudar ninu awon idile Larubawa, awon idile yii a maa fun Rajab ni owo ati aponle pupo ju idile miran lo, idi niyii ni Ojise Olohun fi pe ni Rajab Mudar.
Osu Al-Israa' ati Al-Mi`raj
Ninu osu alaponle yii ni irin-ajo nla Al-Israa' and Al-Mi`raj wa ye, irin-ajo ti Olohun fi se alekun aponle ati iyi fun Anabi Re. Ni ijeri si oro yii, Olohun so ninu oro Re wipe:
{ Mimo ni fun Eniti O je ki olujosin Re rin loru lati Mosalasi Abowo lo si Mosalasi ti o jinna rere ti Awa fi ibukun yi ka re ki Awa le fi ninu awon ami Wa han a. Dajudaju on (Olohun) ni Olugboro, Oluriran.} ( Suratu Israai 17: 1)
Olohun fi ariseemo irin-ajo yii pon Asiwaju Eda le, gbogbo ohun to pamo sinu samo mejeje ni Oluwa fi han Ojise Re.
O dara pupo lati gba awe ninu osu yii, oore ati ibunkun wa ninu awon ojo Rajab. Ki a sit un ma fi osu yii ranti oore ti Olohun se fun Ojise Re ati gbogbo Musulumi nipa irn-ajo nla ti o waye ninu osu na.
Olohun ni onimo julo
0 التعليقات:
Post a Comment